̀dà Àwòrán Aládùn Gérard Quenum

Kílo jọra láàrin àwọn ìgbòkun ìkun àwòrán méjì ti akun-ọ̀dà Gérard Quenum ọmọìlú Benin ? Èkíní, ọ̀dà àwòrán ní ààlà (akun-èsè yí fẹ́ràn áwọ́ dúdú àti funfun àti àwọn àwọ̀ pàtàkì tí a lè dàpọ́). Ṣugbọ́n àwọn àwòrán tí o fí àwọ̀ dúdú kun dábi òjìji. Èkéjì jẹ nípa ọ̀rọ̀ tí akun-ọ̀dà yí fẹ́ràn gan - ọ̀rọ̀ ọkọ́ ti gbogbo ènìyàn tí o jẹ àpẹrẹ ìṣíni sí ilẹ̀ míràn àti ìrìn káàkiri. Nínu iṣẹ́ ọnà méjì yí tí o dá ní ọdún 2013, Gérard Quenum ṣe ifihànsí gbigbé rẹ̀ ní Lọndọnu nínu Taxi Londres, àti gbígbe rẹ̀ ní Benin àti Áfríkà nínu Taxi brousse. Àwọn taxi brousse jẹ ọkọ̀ akérò tí a fímọ ilẹ̀ Áfríkà. Pẹ̀lú bi wọn ṣe kére tó, àwọn ọkọ̀ yí ma n gbé ẹrù nlá tí wọn ma so s'orí ọkọ̀ náà. Gérard Quenum fi éyì hàn pẹ̀lú ẹyẹ tí o wà nínu ilé ẹyẹ. Ènìyàn tí o wà níta ọkọ̀ náà jẹ àwòránàpẹrẹ gbogbo èrò tì o jọ mọ ayé pálápálá níbi ọkọ̀ akéròní Áfríkà.

̀dà Àwòrán Aládùn Samuel Fosso

Wò àwọn ènìyàn àlàwọ̀ wọ̀nyí tí o wà lókè! Ajalèlókun? Olowó? Onìgbàlà òkun, onísẹ́ òkun, akọrin, olónjẹ Áfríkà? Ìkaánà lorí ọ̀rọ̀ náà: aláyàwòrán tí o wà nínu gbogbo àwọn ayàwòrán yí tí o dàbi wípe o ṣẹṣọ̀ pa-radà, tí o sì jẹ́ kí o jọmọ́ oríṣiríṣi ènìyàn lojú-ayé. Àwọn ayàwòrán mẹ́wà yí wà nínu eré TATI tí o ṣe dídálẹ̀ ní ọdún 1997 tí o wà fún ìbéèrè nígbà àjọ̀dún àádọ́ta ṣọ́ọ̀bù nlá olókìkì tí o wà ní adúgbò Barbès ní Parisi. Eré TATI lẹ́hin yẹ̀yẹ́ rẹ̀ ní ohun tí o ṣe pàtàkì: Samuel Fosso lò ayáwòrán rẹ̀ àti ẹṣọ̀ ṣíṣé láti fí ṣeré ẹyà àwọn ilù apáìwọ̀ọrùn tàbí eré tí ìṣẹ̀lù.

Samuel Fosso jẹ́ ọmọ ilù Kamẹrúùn tí o ngbé ní Bangui, ní Apa Arin Áfríkà láti ọjọ́pípé, kò sì dáwọ dúro níṣẹ́ ṣíṣé tí ayàwòrán.

̀dà Àwòrán Aládùn Bruce Clarke

jẹ kí a lọ rí àwọn iṣẹ́ àwòrán méjì tí eré ẹlẹ̀ṣẹ́: L’impensable, tí ọdún 2005 àti The game begins, tí ọdún 2011. Sún mó ibi kí o rí ọ̀nà iṣẹ́ pàtàkì Bruce Clarke, oníṣẹ́-ọnà ilù Gẹ̀ẹ́sì tí o sì jẹ ọmọìlú Gúúsù Áfríkà. O ma n so àwòrán kíkùn pọ̀ mọ àwòrán alaṣàkópọ̀, ọrọ̀ mọ àwòrán, o dẹ̀ ma n gbé wọn léra wọn pẹ̀lú ìpari tí o dán bí gíláàsì tí o lè fí riran. Bruce Clarke, oníṣẹ́-ọnà tí o fí ọkàn sí ohun tí o n ṣẹ́lẹ̀ l'àwùjọ, ba wa sọ̀rọ̀ nípa eréádíjé tí o ní látiṣe pẹ̀lú ìtàn ìjà fún ẹ̀tọ́ ọmọìlú. Ní Amẹ́ríkà, wọn dádúró lòfin eré ìjà láàrin àwọn ènìyàn dúdú àti àwọn ènìyàn pupa. Ní ọdún 1910, Jack Johnson tí o jẹ ènìyàn dúdú eléré ìjà àti aṣẹ́gun gbogbo ayé, ò ní òkíkí ní ojú òfin. A lè sọ wípe ìjà fún òkíkí rẹ̀ jẹ́ àṣeétẹ̀ lorí ọ̀rọ̀ ìdọgba láàrin àwọn dúdu àti funfun. Léhin igbà tí wọn jẹ́ kí o jà pẹ̀lú ènìyàn funfun, íròhìn ìṣẹ́gun rẹ dá ìjà ìkórira ẹlomiran nítóri ìràn káàkiri ìlú. Eré ìjà di ọ̀nà èkejì ní ọgọrun ọdún ogún tàbí nígbà mì, ọ̀nà ṣoṣo láti di ènìyàn nlá l’áwùjọ. Bruce Clarke sọ̀rọ̀ nípa eré ẹlẹ̀ṣẹ́ bí iìjà fún ipò tí o n ṣẹlẹ ní áwùjọ wa lóònì.

̀dà Àwòrán Aládùn Frédéric Bruly Bouabré

O n wò àwòrán La légende de Bekora pẹ̀lú aṣàwòrán 12 kékeré ti Frédéric Bruly Bouabré, ọmọìlú Kót d'ivoa, oníṣẹ́-ọnà tí o ṣaláìsì ní ọdún 2014. Tí o ba tunwò, wa rí pe o da ayàwòrán àti ìkọ́wé pọ̀ lorí páli, pẹ̀lú ohun èlò ìyàwòrán, efun ọlọdà, àti yíìnkì. Àwòrán yí patàn nípa ọlọ́dẹ Bekora tí o padè Gbli, ejò tí o gbàlà nígbà tí o n ṣọdẹ. Láti dúpe, Gbli sọfún wípe òun a fún ní gbogbo ohun tí o bá fẹ́. Bekora sì béèrè áìkù. Gbli dẹ̀ fi éwé ologùn àti bí o ṣe ma lò hàan. Nígbà tí Bekora padà sílé, o sọ ohun tí o ṣẹlẹ̀ fún ìyawó rẹ̀, o sì sọ fúun ṣe ohun tí Gbli sọ fún lojú oorun, gẹgẹbi àkíyèsí Gbli. Léhin wákàtí diẹ, Bekora di òkúta. Láti ìtàn yí ní òwe yí tí wa: "Ẹ́ni wa áìkù dí òkúta ». Àwọn àwòrán méjìlá yí tí o tán mọ àwọn àwòrán míràn ti Frédéric Bruly Bouabré fí ṣe eré lapápọ̀ jẹ "Connaissance du monde", ilé-iṣẹ́ ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ gbogbo ayé tí oníṣẹ́-ọnà yí ṣe fún fẹ́rẹ̀ to aàbọ ọgọrun ọdún.

̀dà Àwòrán Aládùn Cyprien Tokoudagba

Jẹ ka pàdé Cyprien Tokoudagba! Iṣẹ́ rẹ̀ ní ohun láti ṣe pẹ̀lú ìtàn àṣà àti àṣà orílẹ̀-èdè Dahomey. Kílo rí? Ẹfọ̀n? Éso? Bẹni ṣùgbọ́n wọn jú bẹẹ lọ. Wọn jẹ àpẹrẹ àwọn ọba ilẹ̀ Dahomey tí o ní ìròiyè inú nípa atàgbàrán ìgbàgbọ́ àti ìtàn lorí ìgbòkun ìkun àwòrán akrilik, tí Cyprien Tokoudagba oníṣe-ọnà ọmọìlú Benin tí o ṣaláìsì ní ọdún 2012, fi-han. Ẹfọ̀n, tí o yà ní ọdún 2005, jẹ àpẹrẹ ọba Guézo. Gẹgẹbi ẹranko alagbára, o fihàn wípe kò si ohun tí o lè dádúro ní ohunkóhun tí bá fẹ́ ṣe. Labẹ ẹfọ̀n náà, a rí odo, tí o jẹ àpẹrẹ ìlú Abomey, ólórí ìjọba ìlú náà. Éso tí o yà ní ọdun 2006 jẹ àpẹrẹ ọba Agonglo. Ní èdè ìlú náà, wọn pe éso igi ọ̀pẹ yí ní Agon. Àwọn àpẹrẹ wọ̀yí tọkasí òwe yí - "mọ̀nàmọ́ná ṣa sorí igi ọ̀pẹ, ṣùgbọ́n igi ọ̀pẹ yẹ ». Eyí jẹ ọ̀rọ̀ nípa agbára ọba láti yẹ kòtò àti láti ṣẹgún wàhálà ìjọba rẹ̀.

̀dà Àwòrán Aládùn George Lilanga

George Lilanga jẹ oníṣe-ọnà Tànsáníà tí o ṣaláìsì ní ọdún 2005. Àwọn àwòrán alàwọ́ ìmọlẹ́ rẹ̀  lorí ìkùnláwọsì tí o jẹ àpẹrẹ ìtàn aṣà ìlú rẹ̀ ní Makondés - àwọn ènìyàn tí o n sọ èdè bantoue, tí wọn sì n gbe - ní pàtàkì - láàrin iháà gùùsù àti apa ìwọ̀ọrùn ní Tànsáníà àti Mòsámbìk. O ṣe túmọ̀ àwọn ìtàn náà nínu àwọn ayàwòrán akrílìk mẹ́rin náà ní ọdún 1998. A rí ayé rúdurùdu àti apapọ̀ àwọn kìnìhún àti iwin. Òmìnira tí a rí nínu àwọn àwòrán yí ṣàtúnṣe lorí iṣẹ́-ọwọ líle pẹ̀lú ẹdà dúdú.

̀dà Àwòrán Aládùn Omar Victor Diop

Káàbọ̀ sí Le studio des vanités. Àwọn ayàwòrán mẹ́ta tí ọdún 2011 yí jẹ ará ọkan láàrin àwọn iṣẹ́-ọwọ Omar Victor Diop, alayàwòrán ọmọìlú Sẹ̀nẹ̀gàl. Wa dá àrà àwọn ayàwòrán yí mọ̀: ayàwòrán tí o fihànsí pàtàkì aṣọ àti èròjà, àtii ilẹ̀. Wọn ṣàtúnṣe ẹ̀ṣọ̀ titun tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn, tí o sì wà l'ọkàn Omar Victor Diop nínu iṣẹ́-ọnà àti ẹ̀ṣọ̀. Nínu gbogbo àwọn ayàwòrán wọnyí ni àwọn elére àṣà ilẹ̀ Áfríkà, tí o jẹ àwòrán tí o fihàn àgbáyé tí o dá - àgbáyé tí o n jìkàdì láti di èdà titun nílẹ̀ Áfríkà.

̀dà Àwòrán Aládùn Soly Cissé

Áwọn àwòrán mẹ́ta tí Soly Cissé oníṣe-ọnà ọmọìlú Sẹ̀nẹ̀gàl jẹ ara àwọn iṣé àwòrán tí o n jẹ Bestiaire, tí o kùn sorí ìwé pẹ̀lú efun ọlọdà, ọdà akrílìk ní ọdún 2009. A rí àwọn àjèjì tí n banilẹ̀rù ní àrà tí ò dọ́gba. Nínu àwòrán yí tí ò nì nkankan láti ṣe pẹ̀lú ìwọ̀n, Soly Cissé gbe ilé-ayé tí o fẹràn ohun titun (o fihàn pẹ̀lú nọ́mbà àti kóòdù pẹpẹ tí o wà nínu àwọn àwòrán rẹ̀) àti ilé-ayé àjèjì (níbi tí ẹrank n jọba) le ra wọn lórí.Oníṣẹ́-ọnà yí, bí o ṣe kó àwọn èdà oríṣiríṣi pọ̀, n ṣe ìbẹ́ẹ̀rè lórí ilé-ayé àwọn ènìyàn nínu àwùjọ tí kún pẹ̀lú ìparadà.

̀dà Àwòrán Aládùn Romuald Hazoumè

Wò dada àwọn ìgbòkun ìkun àwòrán mẹ́jì l'átọwọ oniṣé-ọnà ike Romuald Hazoumè ọmọìlú Benin. Níbo ní àwọn ọdà àti pàntí lórí ìgbòkun ìkun àwòrán yí tí wa? Oníṣẹ́-ọnà yí lò ọdà tí ìwà èdà bí: ìyẹ̀pẹ̀, ìgbẹ̀ màluu, àwẹ búlúù… Àwọn àmì nkọ? Igun mẹ́rin, óbíríkítí, ìlà àyíká, ìlà bí omi òkun, àmì ọfà: kíni ìtúmọ̀ wọn ? Romuald Hazoumè fi àwọn àmì ifá sínu àwòrán méjì yí Lete-meji tí ọdún 1993 àti La reine tí ọdún 2006, hàn sáyẹ́nsì ifá nílẹ̀ Yorùbá. O fi àwọn àmì yí hàn bí àwọn Yòrúba ṣe mọ ayé, ọkankan àwọn àmì yí sì jẹ ayé míràn. Romuald Hazoumè lò ilé-ayé yí bí ohun àṣà láti ṣe àwọn ìbéèrè kan nípa ilé-ayé òun, ọjọ iwájú ilẹ̀ Áfríkà, tàbí ayé tí o n paradà. Oníṣe-ṣnà yi pe àṣa yí ní tirẹ̀, pe ara rẹ̀ ní "Arẹ", oníṣe-ṣnà Yorùbá tí n kákiri pẹlú ìròhìn àṣà rẹ̀.

̀dà Àwòrán Aládùn J.D.’Okhai Ojeikere

O Wa ní iwájú ayàwòrán mẹta tí o jẹ ara iṣẹ́ àwòrán  láti ọwọ alayàwòrán J.D.’Okhai Ojeikere, ọmọìlú Nàìjíríà. Oníṣẹ́-ọnà yí, tí o mọ nípa iṣẹ́ ayàwòrán láti ṣe itọjú àṣà ibilẹ̀, ṣe àṣàjọ àwọn àwòrán 1000 oríṣiríṣi irun ẹṣọ̀ àwọn obìrin Nàìjíríà nínu àwọn àwòrán tí o ṣe ní ọdún 1968 si ọdún 1999. J.D.’Okhai Ojeikere fi àwọn àwòrán rẹ̀ ṣe irantí àwọn oríṣiríṣi àṣà irun ẹṣọ. Nílẹ̀ Áfríkà, irun jẹ ohun ẹṣọ. Irun sì jẹ àpẹrẹ ipò obirin ní àwùjọ, o sì jẹ fún oríṣiríṣi ìṣẹlẹ̀. Àwọn obirin ma n kọ ẹhin sí ẹrọ́ ìyàwòrán kí ènìyàn kankan ma dá wọn mọ, wọn o ki n fi ojú hàn nígbà púpọ́. Ayàwòrán wò irun ori láti ṣe ifihàn iṣẹ́-ọwọ irun dìdì. Àwọn àwòrán Hair style jẹ èyí tí o lókìkì jù láàrin àwọn àwòrán tí J.D.’Okhai Ojeikere yà níta ibi ilé-iṣẹ́ rẹ̀ fún rírà. Fún oníṣẹ́-ọnà yí, àwọn àwòrán yí jẹ didá nítorí ìfọwọ́sowọ́pọ: ẹ̀bùn àyàwòrán irin àti yíyàn oníbàárà tí o ní irun didi lórí.

WakponYOR.html
WakponInfo.html
iWakponInfo.html

WAKPON – Ilé-àkójọpọ̀ l'òde jẹ ètò àìrídìmú Ilé-iṣẹ́Zinsou.